Joshua 13:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé.