Joshua 13:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
láti odò Ṣíhónì ní ìlà oòrùn Éjíbítì sí agbégbé Ékírónì ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kénánì (agbégbé ìjòyè Fílístínì márùnún ní Gásà, Ásídódù, Áṣíkélónì, Gátì àti Ékírónì ti àwọn ará Áfítì):