Joshua 13:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ìdajì Gílíádì, àti Ásítarótù àti Édírérì (àwọn ìlú ọba Ógù ní Básánì). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírì, ní agbo ilé ní agbo ilé.