Joshua 13:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbégbé òkè, láti Lẹ́bánónì sí Mísiréífótì-Máímù, àní, gbogbo àwọn ará Sídónì, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,