Joshua 14:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kénánì, tí Élíásérì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Ísírẹ́lì pín fún wọn.