Joshua 14:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí OLÚWA ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè. Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún.