Joshua 14:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí OLÚWA ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Ánákì ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì se olódi, ṣùgbọ́n bí OLÚWA ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”