Joshua 14:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Meji ni wọ́n pín àwọn ẹ̀yà Josẹfu sí, àwọn ìpín mejeeji náà ni ẹ̀yà Manase ati ti Efuraimu. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ìpín kankan ninu ilẹ̀ náà, ṣugbọn wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú láti máa gbé, ati pápá, ibi tí wọ́n ti lè máa da mààlúù wọn, ati gbogbo ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì di ẹ̀yà méjì, Mánásè àti Éfíráimù. Àwọn ọmọ Léfì kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.