Joshua 14:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Júdà wá sí ọ̀dọ̀ Jósúà ní Gílígálì. Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí OLÚWA sọ fún Mósè ènìyàn Ọlọ́run ní Kadesi-Báníyà nípa ìwọ àti èmi.