Joshua 14:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run mi.