Joshua 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà, Mósè búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà Pẹ̀lú OLÚWA Ọlọ́run mi.’