Joshua 15:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.