Joshua 15:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dáhùn pé, “Ṣe ojúrere àtàtà fún mi. Níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Negefi fun mi ní ìsun omi pẹ̀lú.” Báyìí ni Kélẹ́bù fún un ní ìsun omi ti òkè àti ti ìṣàlẹ̀.