Joshua 15:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì lọ sí gúsù Sikopioni Pasi lọ títi dé Sínì àti sí iwájú ìhà gúsù Kadesi Báníyà. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hésórónì lọ sí Ádárì, ó sì tún yípo yíká lọ sí Kákà.