Joshua 15:63 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Júdà kò lè lé àwọn ọmọ Jébúsì jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jérúsálẹ́mù. Àwọn ará Jébúsì sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Júdà títí dí òní.