Joshua 15:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Bẹni Hínómù ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúsù ti Jébúsì (tí í ṣe Jérúsálẹ́mù). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hínómù ní òpín àríwá àfonífojì Réfáímù.