Joshua 15:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Néfítóà, ó sì jáde sí ìlú Okè Éífírónì, ó sì lọ sí apá ìṣàlẹ̀ Báálà, (tí í ṣe, Kiriati Jéárímù).