Joshua 16:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìpín ti Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò, ó sì la aṣálẹ̀ kọjá láti ibẹ̀ sí ọ̀nà ihà sí òkè ìlú Bẹ́tẹ́lì.