Joshua 16:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti Tápúà ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Ráfínì, ó sì parí ní òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé.