Joshua 17:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ní ìpín ẹ̀yà Mànásè tí í ṣe àkọ́bí Jósẹ́fù, fún Mákírì, àkọ́bí Mánásè. Mákírì sì ni babańlá àwọn ọmọ Gílíádì, tí ó ti gba Gílíádì àti Básánì nítorí pé àwọn ọmọ Mákírì jẹ́ jagunjagun ńlá.