Joshua 17:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìhà gúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Éfúráímù, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Mánásè. Ilẹ̀ Mánásè dé òkun, Ásérì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà Ísákárì jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn.