Joshua 17:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joṣua dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá pọ̀, ẹ lọ sí inú igbó, kí ẹ sì gba ilẹ̀ níbẹ̀ ninu ilẹ̀ àwọn ará Perisi ati ti àwọn Refaimu, bí ilẹ̀ olókè ti Efuraimu kò bá tóbi tó fun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si da wọn lohùn pe, Bi iwọ ba jẹ́ enia nla, gòke lọ si igbó, ki o si ṣanlẹ fun ara rẹ nibẹ̀ ni ilẹ awọn Perissi ati ti Refaimu; bi òke Efraimu ba há jù fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóṣúà dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Éfúráímù bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì sán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Pérísì àti ará Réfì.”