Joshua 17:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ẹ̀yà Josẹfu bá dáhùn pé, “Ilẹ̀ olókè yìí kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kenaani tí ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tí wọn ń gbé Beti Ṣani, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé àfonífojì Jesireeli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Josefu si wipe, Òke na kò to fun wa: gbogbo awọn ara Kenaani ti ngbé ilẹ afonifoji si ní kẹkẹ́ irin, ati awọn ti mbẹ ni Beti-ṣeani, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ti mbẹ ni afonifoji Jesreeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Jósẹ́fù dáhùn, “Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kénánì tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Bẹti-Ṣánì àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní àfonífojì Jésírẹ́ẹ́lì ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.”