Joshua 17:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹ̀yin ni ẹ óo ni agbègbè olókè wọnyi pẹlu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ gbà á, kí ẹ sì ṣán an láti òkè dé ilẹ̀ títí dé òpin ààlà rẹ̀. Ẹ óo lé àwọn ará Kenaani jáde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn, tí wọ́n sì jẹ́ alágbára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ilẹ òke yio jẹ́ tirẹ; nitoriti iṣe igbó, iwọ o si ṣán a, ati ìna rẹ̀ yio jẹ́ tirẹ: nitoriti iwọ o lé awọn ara Kenaani jade, bi o ti jẹ́ pe nwọn ní kẹkẹ́ irin nì, ti o si jẹ́ pe nwọn lí agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbo jẹ́ tiyín pẹ̀lú. Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátapáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kénánì ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, ṣíbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde.”