Joshua 17:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí Sẹloféádì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè, kò ní ọmọkùnrin, bí kò se àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà.