Joshua 17:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì, àti àwọn olórí wí pé, “OLÚWA pàṣẹ fún Mósè láti fún wa ní ìní ní àárin àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLÚWA.