Joshua 17:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilẹ̀ ti Manase bẹ̀rẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikimetati tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Ṣekemu, ààlà rẹ̀ tún lọ sí apá ìhà gúsù ní apá ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ń gbé Entapua.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbégbé Mánásè sì fẹ̀ láti Áṣírìu títí dé Míkímẹ́tatì ní ìlà oòrùn Sékémù. Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tápúà,