Joshua 17:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààlà náà sì tún tẹ̀ṣíwájú lọ sí gúsù dé Kana-Ráfínì. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Éfúráímù wà ní àárin àwọn ìlú Mánásè, ṣùgbọ́n ààlà Mánásè ni ìhà àríwá Ráfínì, ó sì pin sí òkun.