Joshua 18:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúsù ní ọ̀nà Lúsì, (èyí ni Bẹ́tẹ́lì) ó sìdé Afaroti-Ádárì, ní orí òkè tí ó wà ní gúsù Bẹti-Hórónì