Joshua 18:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti òkè tí ó kọjú sí Bẹti-Hórónì ní gúsù ààlà náà yà sí gúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Báálì (tí í ṣe Kiriati-Jéárímù), ìlú àwọn ènìyàn Júdà. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.