Joshua 18:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni Ṣẹ́mẹ́sì, ó tẹ̀ṣíwájú dé Gélíótì tí ó kọjú sí òkè Pasi Ádúmímù, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Okúta Bóhánì ọmọ Rúbẹ́nì.