Joshua 18:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sélà, Háléfì, ìlú Jébúsì (tí íse Jérúsálẹ́mù), Gíbíà àti Kíríátì, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn. Èyí ni ìní Bẹ́ńjámínì fún ìdílé rẹ̀.