Joshua 18:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Júdà dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúsù àti ilé Jósẹ́fù ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá.