Joshua 18:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò ní ìpín ní àárin yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. OLÚWA ni ìní wọ́n. Gádì, Rúbẹ́nì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti fi fún wọn.”