Joshua 19:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Ṣùgbọ́n àwọn ará Dánì ní ìsoro láti gba ilẹ̀-ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Lẹ́ṣẹ́mù, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Lẹ́sẹ́mù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì orúkọ baba ńlá wọn).