Joshua 19:51 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ati àwọn àgbààgbà ninu ẹ̀yà àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹ́ gègé láti pín ilẹ̀ náà ní Ṣilo níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; wọ́n sì parí pípín ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Élíásárì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Ísírẹ́lì fi ìbò pín ní Sílò ní iwájú OLÚWA ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.