Joshua 19:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Apá kan ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Simeoni. Ìpín ti ẹ̀yà Juda tóbi jù fún wọn, nítorí náà ni ẹ̀yà Simeoni ṣe mú ninu tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A mú ogún ìní àwọn ọmọ Símíónì láti ìpín Júdà, nítorí ìpín Júdà pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Símíónì gba ìní wọn ní àárin ilẹ̀ Júdà.