Joshua 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jóṣúà ọmọ Núnì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àsírí láti Ṣítímù. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jẹ́ríkò.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé aṣẹ́wó kan, tí à ń pè ní Ráhábù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.