Joshua 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa ti gbọ́ bí OLÚWA ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì; àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Ṣíhónì àti Ógù, àwọn ọba méjèèjì ti Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì, tí ẹ̀yin parun pátapáta.