Joshua 20:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ìlú ọ̀hún ni ìlú ààbò tí wọ́n yàn fún àwọn ọmọ Israẹli, ati fún àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ààrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sí èyíkéyìí ninu wọn, yóo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé ní àárin wọn tí ó sèèsì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.