Joshua 21:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ní Ṣilo ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sọ fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose pé kí wọ́n fún wa ní ìlú tí a óo máa gbé ati pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “OLÚWA pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”