Joshua 21:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún àwọn ọmọ Geriṣoni ninu ìdílé Lefi ní àwọn ìlú wọnyi: Golani ní ilẹ̀ Baṣani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Golani yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati Beeṣitera pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìlú meji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Gáṣóní idile àwọn ọmọ Lefi ní wọ́n fún lára: “ìdajì ẹ̀yà Mánásè, Gólánì ní Básánì (ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Be Ésítarà pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ méjì;