Joshua 21:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili. Kedeṣi yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, wọ́n tún fún wọn ní Hamoti Dori, Katani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati inu ẹ̀ya Naftali, Kedeṣi ni Galili pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Hammotu-dori pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Kartani pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ara ẹ̀yà Náfítanì ni a ti fún wọn ní Kedeṣì ní Gálílì (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hámótì Dórì àti Kárítanì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́ta.”