Joshua 21:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti sèlèrí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀ta wọn tí ó lè dojú kọ wọ́n. OLÚWA sì fi gbogbo àwọn ọ̀ta wọn lé wọn ní ọwọ́.