Joshua 22:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó bá jẹ́ pé ilẹ̀ yín kò mọ́ tó láti máa sin OLUWA níbẹ̀ ni, ẹ rékọjá sinu ilẹ̀ OLUWA, níbi tí àgọ́ rẹ̀ wà, ẹ wá gba ilẹ̀ láàrin wa. Ẹ ṣá má ti ṣe oríkunkun sí OLUWA, tabi kí ẹ sọ gbogbo wa di olóríkunkun nípa títẹ́ pẹpẹ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní OLÚWA, ní ibi tí àgọ́ OLÚWA dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí OLÚWA tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ OLÚWA Ọlọ́run wa.