Joshua 22:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú OLÚWA.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù OLÚWA.