Joshua 22:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún OLÚWA ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti OLÚWA.’