Joshua 22:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹrẹ pẹpẹ OLÚWA, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrin àwa àti ẹ̀yin.’