Joshua 22:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kénánì láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ní Gílíádì, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.