Joshua 22:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ náà dùn mọ́ àwọn ọmọ Israẹli ninu, wọ́n sì fi ìyìn fún Ọlọrun; wọn kò sì ronú ati bá wọn jagun mọ́, tabi àtipa ilẹ̀ wọn run níbi tí wọ́n ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohun na si dùnmọ́ awọn ọmọ Israeli; awọn ọmọ Israeli si fi ibukún fun Ọlọrun, nwọn kò si sọ ti ati gòke tọ̀ wọn lọ ijà, lati run ilẹ na ninu eyiti awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ngbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run. Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ń gbé.